The Pin Point News
Uncategorized

Ile-ẹjọ kotẹmilọrun yọ Idọlọfin loye gẹgẹ bíi ọba Ararọmi-Ọbọ l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ kotẹmilọrun kan tio wa ni ilu Ado-Ekiti ni ipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ki Ọgbẹni Roland Ojo Olowokere kuro lori oye gẹgẹ bii Ọba ilu Ararọmi-Ọbọ ni ijọba ibilẹ Irepọdun/Ifẹlodun, ni ipinlẹ Ekiti.

Ile-ẹjọ naa ti Onidajọ Bọde Adegbehingbe, ṣe akoso rẹ tun paṣẹ pe ki Ọgbẹni Olowokere, tio soju idile Idọlọfin kuro lori oye pẹlu alaye pe idile naa ko lẹtọ lati wa lori oye gẹgẹ bíi ọba  ilu naa. 

Bakan naa ni Onidajọ Adegbehingbe tun paṣẹ pe ki idile Idọlọfin san ilaji miliọnu fun idile Ẹlẹ́mẹ̀bọ̀ ti lẹtọ si oye Ọba ilu Ararọmi-Ọbọ.

Ninu iwe ipẹjọ kan ti awọn awọn mẹta kan pee lorukọ ẹbi Ẹlẹmọbọ, awọn mẹta naa ni, Adenikẹ Ogundahunsi, Ebenezer Ojo ati Ijọba ibilẹ Ado, awọn ti wọn pe lẹjọ naa ni Ọgbẹni Roland Ojo Ijọba ibilẹ Irepọdun/Ifẹlodun ati agbefọba agba ti ipinlẹ Ekiti.

Ṣe ṣaaju ni ile-ẹjọ giga kan lọdun 2021 ti kọkọ da ẹjọ naa pe idile Idọlọfin ko lẹtọ si oye ilu naa, ati pe idile Ẹlẹ́mọbọ̀ gan ni idile tio lẹtọ si ipo Ọba ilu naa.

Ṣugbọn nigba ti idajọ naa ko tẹ ẹbi Idọlọfin lọrun ni wọn gba ile-ẹjọ kotẹmilọrun lọ, ṣugbọn ile-ẹjọ; kotẹmilọrun tun da wọn lẹbi pe ẹbí Ẹlẹ́mẹ̀bọ̀ gan nio lẹtọ lati wa lori oye naa.

Adajọ naa nio ṣe alaye pe ilu iṣẹmbaye Ọra tio wa lara ilu Ado-Ekiti ni ibi ti awọn eyan ilu Ararọmi-Ọbọ ti wa ki wọn to wa tẹdo si ojuko ti wọn wa yii.

Lakoko ti ẹjọ yii fi ni ile-ẹjọ ni ilu Ararọmi-Ọbọ fi pin si meji pẹlu bii Ọgbẹni Roland Ojo Olowookere, tio ṣoju idile Idọlọfin ṣe nṣe akoso igun lan ninu ilu, bakan naa ni idile Ẹlẹ́mẹ̀bọ̀ naa ni adele Oba tiwọn, ti orukọ rẹ njẹ Ọmọ Obabinrin Adenikẹ Ogundaisi.

Lakoko tio mba oniroyin soro, ni kete ti igbẹjọ naa waye tan, Adele Ọbabinrin naa tio tun nṣoju idile Ẹlẹ́mẹ̀bọ̀, Adenikẹ Ogundaisi, dupẹ lọwọ ile-ẹjọ naa fun ṣiṣe idajo ododo.

Ọmọ Ọbabinrin Ogundaisi ṣalaye pe idile Ẹlẹ́mẹ̀bọ̀ nio tiwa ni ile-ẹjọ lori ọrọ ipo Ọba ilu Ararọmi-Ọbọ lati ọdun 1991, pẹlu bii idile Idọlọfin ko ṣe gba lati kuro lori oye ipo Ọba ilu Ararọmi-Ọbọ.

Related posts

US PRESIDENTIAL ELECTION: Trump Defeats Harris In Historic Comeback

Editor

NBA President Refutes Claims of Widespread Judicial Corruption in Nigeria

Editor

EKSU FEES: “Marginal Increase Affects Only Freshers” — Management Clarifies

Editor
error: Content is protected !!